BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìdí rèé táwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi lè gba ẹ̀jẹ̀ ará wọn pamọ́ báyìí láti lò fún ìtọ́jú tó bá nílò kí wọ́n gbẹ̀jẹ̀
Fun ọpọlọpọ ọdun, alaisan to ba jẹ ẹlẹrii Jehofa tawọn dokita ba sọ fun un wi pe o nilo ki wọn fa ẹjẹ si i lara nile iwosan ko ni gba ki wọn ṣe bẹẹ tori o tako igbagbọ wọn.
Ọmọ ìyá kan náà méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá iná l'Ondo, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe aibikita obi awọn ọmọ naa lasiko ti wọn n dana lọwọ lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Toyosi Adesanya, òṣèré tíátà Yoruba, di ọlọ́mọ láyé fún ìgbà àkọ́kọ́ nípasẹ̀ ìlànà abánigbóyún
Biola Bayo, oṣere tiata mii lo kede iroyin naa loju opo ayelujara Instagram rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe tọkọtaya naa di ọlọmọ laye ni ilana abanigbe oyun.
Àwọn àgbẹ̀ oníkòkó méjì tó ṣẹ́kù sí àkàtà àwọn ajínigbé nínú mẹ́rin tí wọ́n jí gbé níléeṣẹ́ kòkó n'Ibadan ti gba ìtúsílẹ̀
Agbẹ onikoko kan ti ori ko yọ ninu iṣẹlẹ naa sọ pe inu igbo lawọn agbesunmọmi naa gba wa, ti wọn si di ọkọ wọn lọna lasiko ti wọn n lọ si ẹka eto ilera ọgba ajọ naa.
Fídíò, ''Ogún ọdún ni mo fi wá ọmọ, IVF mẹ́jọ ni mo ṣe tó kùnà, 'surrogacy' ni mo fi padà bí ìbejì'', Duration 5,56
Arabinrin Emily Ejiovi sọ pe oun nikan loun o lọmọ ninu gbogbo awọn ọmọ iya oun. O ni igba mẹjọ ni oyin bajẹ lara oun, bakan naa loun ṣe eto IVF lati bimọ nigba mẹjọ eyi to kuna.
Ohun tí a mọ̀ nípa ẹjọ́ lórí àwọn dúkìá Alao-Akala ní Naijiria, Ghana, UK àti l'Amẹrika tí ẹbí ń jà lé lórí
Oluwatoyin Alao Aderinto ọmọbinrin akọkọ oloogbe sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn kan ti ta diẹ ninu awọn dukia ọhun lai jẹ ki oun mọ, ati pe wọn tun n gbiyanju lati ta awọn miran lọwọ lọwọ.
''Iran ju àdó olóró sí ibùdó ológun Amẹrika àti UK ní Diego Garcia, ṣùgbọ́n kò wọle''
Iwadii BBC fidi rẹ mulẹ pe ado oloro ti Iran ju ọhun ko wọle, ikọlu ọhun si waye ṣaaju ki UK to yonda Amẹrika lati lo ibudo ologun rẹ yin ado oloro si Iran.
Ṣé lóòótọ́ ni pé èpè Alaafin Aole sì ń ja Yorùbá títí di òní?
Itan sọ fun wa pe ọmọ Alaafin Abiodun ni Aole, o si jọba nilu Oyo laarin ọdun 1789 si 1796.
Ìdí rèé tí mo fi so àpò ilé ọmọ mi - Shaffy Bello
Bello sọ èyí níbi ètò rẹ̀ kan tó máa ń ṣe lórí Youtube, Shaffy Bello TV níbi tó ti ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ̀ lásìkò tó ń bímọ lọ́wọ́ àti àwọn ìpinnu tó ṣe láti fètò sí ọmọ bíbí.
Àdó olóró Israel ti ṣekúpa èèyàn 1001 ní Lebanon
Ẹka ilera Lebanon ni eeyan 1,001, to fi mọ ọmọde 111, ti wọn ti padanu ẹmi wọn lati ọjọ keji oṣu kẹta.
Fídíò, DJ Cuppy ṣàlàyé ìdí tí inú rẹ̀ fi dùn pé Ààrẹ Tinubu ṣàbẹ̀wò sí ilẹ̀ UK, Duration 1,57
Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Tinubu ati Iyawo rẹ, Oluremi Tinubu ṣe abẹwo si ilẹ UK lati ki Ọba Charlse III ni ọsẹ yii.
Àwọn tó ń f'owó ran Boko Haram lọ́wọ́ jẹ́ ẹni táwọn aláṣẹ mọ́, wọn ò kàn dárúkọ wọn ni- Buratai
O tẹnu mọ pe awọn eeyan jẹ mimọ, ti wọn si n gbe pẹlu wa lorilẹede Naijiria.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ bàbá ẹni ọdún 74 pẹ̀lú oogun olóró l'Abuja
Papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport to wa niluu Abuja ni ọwọ ti ba baba naa pẹlu Cocaine ti wọn lo jẹ iwọn mọkanla (11 kilograms).
A fẹ́ ṣàfikún iná mọ̀nàmọ́ná tí à ń rà láti Naijiria, iná wọn ń ràn okòòwò àti lílò nílé wa lọ́wọ́ -Orílẹ̀èdè Togo
Adari ileeṣẹ NDPHC, Jennifer Adighije, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku oni, lẹyin ajọsọ ọrọ pẹlu ikọ onina mọnamọna to wa lati orilẹede Togo.
Ilẹ̀ rírì àti omiyalé gbẹ̀mí èèyàn 102 ní Ethiopia
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede pe eeyan ọgbọn lo ku ki iye awọn to ku naa to tun le si laarin wakati mẹrinlelogun.
Ẹ wo bí aláboyún tó ń rọbí lọ́wọ́ ṣe gun ràkúnmí fún wákàtí méje láti dé iléèwòsàn
Awọn obinrin,mọlẹbi ati awọn ojulumọ lo n se iranwọ fun awọn alaboyun naa lati de ileewosan.
Wo ìbéèrè méje tí ọkùnrin kò gbọdọ̀ bi obìnrin
Ohun ti ọkunrin le mu mọra ko si ma binu si rara ni obinrin yoo sọ di babara, to si le binu rangbọndan.
Nítorí ìjàmbá ọkọ̀, ìjọba Ogun fẹ́ẹ́ fòfin de ọjà títà ní Sango Tollgate
Kọmiṣanna eto ayika nipinlẹ Ogun, Ola Oresanya, lo kede eyi lasiko abẹwo rẹ si agbegbe Sango Tollgate.
Gbálé-n-gbáta olóṣooṣù yóò bẹ̀rẹ̀ padà l'Eko lóṣù Kẹ́rin ọdún 2026 – Ìjọba Eko
Gẹgẹ bi Amofin Tokunbo Wahab; Kọmiṣanna fun eto ayika ati omi nipinlẹ Eko ṣe kede loni ọjọ Satide, o ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni atunṣe ayika ti ọpọ eeyan maa n pe ni 'Ẹnfaromẹnta' naa yoo bẹrẹ pada kaakiri Eko.
Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles nígbà kan rí, Henry Nwosu dágbére fáyé
Akẹgbẹ rẹ, Segun Odegbami, lo fi ikede iku agba ọjẹ agbabọọlu ọhun lede lọjọ Abamẹta.
Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ìròyìn pé wọ́n yìnbọn fún Broda Shaggi ní Ogun
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, wọ́n sáré gbé Broda Shaggy lọ sílé ìwòsàn Blooming Care Hospital tó wà ní agbègbè Alakuko ní ìpínlẹ̀ Eko níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ tọ́jú rẹ̀.
Gbajúgbajà olórin ẹ̀mí, Toun Soetan jáde láyé
Ẹni ọdun mẹtalelaadọrin ni Soetan ṣaaju iku rẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii.
Ìgbà wo ni sísọ̀rọ̀ nípa ogun America- Israel àti Iran di ìwà ọ̀daràn ní Naijiria?
Iroyin sọ pe ninu ọsẹ yii, ẹka ọtẹlẹmuyẹ DSS nawọ gan awọn ọdọkunrin meji kan ni Kaduna, lori ohun ti wọn kọ soju opo ayelujara nipa ogun Iran ti America ati Israel bẹrẹ.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
"Ẹ máà bínú bàbá,"- King Mitchy tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Ooni Ile Ifẹ
Ni ọsẹ melokan sẹyin ni iroyin gba ori ayelujara kan nigba ti King Mitchy kede pe oun ti tun awọn ile ẹkọ kan ṣe laarin ọsẹ mẹfa, to si n sọ pe ayipada to ye kooro le waye ni kiakia niwọn igba ti wọn ba ṣe e pẹlu ọkan ijolootọ.
Elena, Gbajúmọ̀ ayélujára kú lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ láti fọn ìdí rẹ̀, ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ náà ṣe sọ, wọ́n ní ohun tó ṣokùnfà ìdí táwọn fi ń ṣe ìwádìí náà ni ìròyìn tó gba orí ayélujára pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí Elena ṣe iṣẹ́ abẹ náà ni ara rẹ̀ kò yá, kó tó di pé ó jáde láyé.
Aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín APC àti Accord ní ìpínlẹ̀ Osun lórí ṣọ́ọ̀bù kíkọ́
Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ede, arakunrin Adeyemi Elliot to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo fẹ ṣe ifilọlẹ ṣọọbu igbalode si ọja Timi to wa ni agbegbe ki awọn janduku to ṣadede da eto naa ru.
Kókó ohun tí Mojtaba Khamenei sọ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó di olórí Iran
Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Mojtaba yóò sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣekúpa bàbá rẹ̀, Ayatollahi Ali Khamenei lọ́jọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì nígbà tí Amẹ́ríkà àti Israel pawọ́pọ̀ ṣe ìkọlù sí Iran.
LPDC da ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìwẹ́ ẹ̀rí NYSC tí wọ́n fi kan igbákejì olórí ilé aṣojúṣòfin nù
LPDC tẹmpẹlẹmọ pé ohun tí wọ́n dá ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀ fún jẹ́ láti ṣe àmójútó àwọn amòfin tó wà lábẹ́ àjọ náà láti ri dájú pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin kẹwàá ìwé òfin ìgbìmọ̀ náà.
Wá wí tẹnu rẹ o! Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ránṣẹ́ pe DPO àgọ́ ọlọ́pàá táráàlú ní afurasí ajínigbé tí sálọ
Yatọ si ọga ọlọpaa ti wọn fi si ahamọ naa, DPO ẹkun naa ati ASP gba iwe ẹsun lati ṣalaye ara wọn lori iṣẹlẹ ọhun pẹlu.
Àwọn olùwọ́de lu ìgboro Aba láti wọ́de pè fún ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu
Gẹgẹ bi BBC Igbo ṣe fidi ẹ mulẹ, aago mẹsan-an aarọ ko ti I lu ti awọn oluwọde naa ti tu si oju opopo pẹlu awọn akọle ọlọkan-o-jọkan ti wọn fi n beere itusilẹ Nnamdi Kanu.
Ó ti yá jù fún kóòtù láti pàṣẹ pé mi ò lè dupò gómìnà mọ́- Aiyedatiwa
Ọjọbọ ana ti idajọ naa waye ni Aiyedatiwa ti fesi pada, nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Channels kan.
Amẹrica kìlọ̀ fáwọn ọmọ orílẹ̀èdè rẹ̀ ní Naijiria, nítorí ìwọ́de Quds àwọn Shiites
Ayajọ Quds jẹ eyi ti awọn ijọ ẹlẹsin Islam IMN ti a tun mọ si Shiites gbe kalẹ.
Amẹrika ṣàlàyé ìgbà àti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí ogun Iran yóò parí
Amẹrika sọ pe ogun naa n lọ bo ṣe yẹ ati wi pe o n yawọ ju bi awọn gan ṣe lero lọ.
Ẹ dákun ẹ gbà mí o, owó dísù ti fẹ́ gbẹ̀mí mi - Èèkàn òṣèré, Kunle Afolayan figbe ta
Oṣere tiata to tun jẹ adari awọn okoowo ati ibudo ti wọn ti n ya sinima ti wọn si tun n ṣe faaji, ṣalaye pe oun n na to miliọnu mọkanla (₦11 million ) lori disu rira laarin ọsẹ mẹrin si marun-un.
Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì akèrò kó s'ódò nílùú Ibadan, èèyàn mẹ́ta kú
Eeyan mẹta lo padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ yii, ti awọn marun un yooku si farapa yanayana.















































































